Orí Kẹẹ̀rin

1 Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ni létí òkun, ọpọ̀ ènìyàn si yíi ká. Ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi tí ó wà lórí òkun, àwọn ènìyàn sì wà ní étí òkun. 2 Ó kọ́ wọn ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú òwe, ẹ̀yí ni ojun tí ó wí fún wọn. 3 “Ẹ fi etí sílẹ̀, afúnrúgbìn náà jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀. 4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. 5 Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Lójúkannáà ó hu jáde, nítorí wọn kò ní erùpẹ̀ púpọ̀. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ. 7 Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò so èso. 8 Òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso bí ó se ń dágbà tí ó sì ń gbilẹ̀, òmíràn so lọ́gbọọgbọ̀n, òmíràn lọ́gọọgọ́ta, àti òmíràn lọ́gọọgọ́rùn-ún.” 9 Ó sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́!” 10 Nígbà tí ó ku Jésù nìkan, àwọn tì ó sú mọ́ ọ àti ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá bi í léèrè ìtumọ̀ òwe. 11 Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a fi adìtú ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n gbọgbọ rẹ̀ jẹ́ ówẹ́ fún àwọn tí ó wà ní ta, 12 wìpé bí wọ́n bá wò, bẹ́ẹ̀ni wọ́n wò, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n gbọ́, bẹ́ẹ̀ni wọn gbọ́, kì yóò yé wọn, dípò bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì yípadà, Ọlọ́run yíò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ” 13 Ó sì wí fún wọn pé, “Sé òwe yìí kò yé e yín ni? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn òwẹ mìíràn? 14 Afúnrúgbìn tí ó ǹ fúnrúgbìn ni ó ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà. 15 Èyí ǐ ni àwọn tó bọ́ sí ojú ọ̀nà, níbi tí a fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ sí, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú ohun tí wọ́n ti gbìn kúrò. 16 Èyí ni àwọn tí ó bọ́ sórí àpáta, nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọrọ̀ náà, lójúkanánáà wọ́n fi ayọ̀ gbà á. 17 Ṣùgbọ́n wọn kò ni gbòǹgbò nínú u wọn, Ṣùgbọ́n wọ́n faradàá fún ìgbà díẹ̀. Lẹ́yìn náà ni wàhálà tàbí inúnibíni dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọ́n subú. 18 Àwọn tí ó kù ni àwọn tí ó bọ́ sáàrín ẹ̀gún. Wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, 19 Ṣùgbọ́n àwọn afẹ́ ayé, ẹtàn ti ọrọ̀ àti àti afẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso. 20 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n sì gbà á, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde- ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín.” 21 Jésù wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wọ inú ilé láti fi sábẹ́ agbọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? a o gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà ni. 22 Nítorí kò sí ohun tí ó pamọ́ tí a kò ní fihàn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, tí kò ní wá sí gbangba. 23 Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́!” 24 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa kíyèsi ohun tí ẹ bà gbọ́, nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n náà ni a ó fi wọ́n fún un yín, a ó sì tún fi kún n fún n yín. 25 Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún sí i, àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ní, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní.” 26 Ó sì tún sọ pé, “Ìjọba Ọlọ́run dàbí okùnrin kan tí ó ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀. 27 Ó ń sùn ní óru àti ní ọ̀sán ó dìde, irúgbìn náà hu jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀. 28 Nítorí tí ilẹ̀ hù èso jáde fún ara rẹ̀: ó mú èéhù ewé jáde, lẹ́yìn náà ní orí ọkà, ní ìparí ní orí ọkà tí ó ti gbó. 29 Nígbà tí èso bá gbó tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòjé bọ inú ọkà náà, nítorí ìkórè ti dé." 30 Ó sì tún wí pé, “Kí ni a ò bá fi ìjọba Ọlọ́run wé, tàbí òwe wo ni a lè fi ṣe àkàwé rẹ̀? 31 Ó dàbí èso hóró musitadi, nígbàt ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. 32 Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ, ó sì yọ ẹ̀ka ńlá, tóbẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí ìbòji rẹ̀. 33 Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti ba àwọn ènìyàn sọrọ̀, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ní òye tó, 34 kò sì bá wọn sọ̀rọ̀ láì lo òwe. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó dá wà, ó sàlàyé gbọgbọ rẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀. 35 Ní ọjọ́ náà, nígbà tí alẹ́ lẹ́, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá sí apá kejì.” 36 Wọ́n fi ọpọ̀ erò sílẹ̀, wọ́n mú Jésù pẹ̀lú wọn, gẹ́gé bí ó ti wà nínú ọkọ̀ ojú omi. Àwọn ọkọ̀ ojú omi míiràn ń bá a lọ. 37 Ìjì líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kún fún omi. 38 Jesu ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i wọ́n wí pé, “Olùkọ́ni, ǹjẹ́ ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ kú?” 39 Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Àlááfíà! Dákẹ́ Jẹ́ẹ́!” Ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà. 40 Lẹ́yìn náà ó wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń bẹrù? Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ síbẹ̀síbẹ̀?” 41 Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, tí ìjì àti Òkun ń gbọ́ tirẹ̀?”