Máákù Orí Kẹta

1 Lẹ́ẹ̀kan si Jésù rìn lọ sínú sínágọ́gù ọkùnrin kan sí wà níbẹ̀ tí apá rẹ rọ 2 Àwọn kan sí wà níbẹ̀ tí wọ́n ń wò pẹ̀lú ìfura bóyá yíò wo okùnrin náà sàn ní ọjọ́ ìsimi kí wọn kí ó le ka ẹ̀sùn sií lọrùn. 3 Jésù sọ fún ọkùnrin tí apá rẹ rọ naa, "Dìde kí o sì dúró ni àárín àwọn ènìyàn yí." 4 Lẹ́hìn náà, ó bi àwọn ènìyàn naa léèré pé: Ǹjẹ́ ó bà òfin mu láti ṣerere ní ọjọ́ ìsimi tàbí ṣe búburú; lati gba ẹ̀mí là tàbí láti pa? Sùgbọ́n wọ́n dákẹ lai sọ̀rọ̀. 5 Ó sí wò yí ká pẹ̀lú ìbínú, àti pé inú rẹ bàjẹ́ nítorí àyà líle wọn, ó sì wí fun okùnrin náà pé, "Na ọwọ́ rẹ jade." Ó sì na ọwọ́ rẹ jáde, ó sí bọ̀ sípò. 6 Àwọn Farisí sì jáde lojukan nàà wọn si bẹ̀rẹ̀ si gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Olùtẹ̀lé Hẹ́ródù bí wọn ó se pa Jésù. 7 Lẹ́yìn naa Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ sì lọ sí odò Gálílì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sí tèlé wọn lati Gálílì ati lati Judia. 8 Láti Jerusalemu ati lati ilẹ̀ àwọn ará Édómù ati lati ẹ̀yìn odò Jódánì wa àti àgbègbè àwọn ará Tireni oun Sidoni wa. Ńigbá tí wọ́n sí gbọ́ àwọn ohun àrà tí à ń ti ọ́wọ rẹ̀ se ọ̀pọ́ àwọn ènìyàn tọọ wa. 9 Ó sì rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ pe kí wọn kí ó seètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan sílẹ̀ fun ohun nítor´ ọ̀pọ̀ ènìyàn, kí wọn kí ó ma bá tẹẹ́ pa. 10 Ńitorí tí o tí wo ọ̀pọ̀ ènìyàn sàn ẹnikọ̀ọ̀kan tí ó ní ìpónjú ń gbìyàjú lati fi ọwọ́ kan an bí o tì wù kí o rí. 11 Ńigbà kuú gbà tí àwọn ẹ̀mì aìmọ́ bá ri, wọn a tẹríba níwájú rẹ pẹ̀lú ariwo, wọn a wípé, "Ìwọ ni Ọmọ Olórun." 12 Ó sì pa wọn lẹ́nu mọ́ pé kí wọn máá se fi òun hàn. 13 Ó sì gùn orí òkè lọ, ó sì pe àwọn tí ò wuú, wọ́n sí tọọ́ wá. 14 Ó yan àwon méjìlá (tí òhun tìkara rẹ̀ pè ní aposteli), kí wọn kí ó le wà pẹ́lu rẹ̀ ati kí òhun le rán wọn lọ lati polongo ìhìn naa 15 ati lati ni àse lati lé àwọn èmí èsù jáde. 16 Lẹ́yìn èyí ó yan àwọn méjìlá: Símónì, ẹni tí ó pè ní Pétérù; 17 Jákọ́bù ọmọ Zébédè ati Jòhánù arákùnrin Jákọ́bù, àwọn ẹni tí ó pè ní Bòánájì, èyí tí ó túmọ̀ sí, àwọn ọmọ àrá; 18 ati Áńdérù, Fílípì, Batolómíù, Mátíù, Tọ́másì, Jákọ́bù ọmọ Áfáúsì, Tádáúsì, Símónì alàjàgbara 19 ati Júdásì Ìskáriọ́tù, ẹni tí yoò fií hàn. 20 Lẹ́yí èyí o lọ́ sí ilé, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kójọ lẹẹ̀kan si tó bẹ̀ tí wọn kòle ràyè fún oúnjẹ. 21 Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ sì gbọ́ nípa ohun tió ń sẹlẹ̀, wọ́n jáde lati lọ mú nitórití wọ́n wípé "kò mọ ohún tió ń se." 22 Àwọn Akọ̀wé tí ó ti Jerusalemu wá wípé, "ẹ̀mí beélsébúbù ti gbé e wọ̀" àti wípé "nípa olórí àwọn ẹ̀mí òkùnkùn ni ó ń lé áwọn ẹ̀mí òkùnkùn jáde." 23 Jésù sì pe àwon ọmọ ẹ̀yìn rẹ sí apá kan ó sì pa òwe kan fún wọn wípé, "bá wo ni sátánì se le maà lé sátánì jáde?" 24 tí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjoba naa kò le serere 25 tí ilé kan bá yapa sí ara rẹ̀ ilé naa kole dúró. 26 Bí sàtánì bá dìde tako ara rẹ̀, a yapa àti pé òhun kí o lè dúró sùgbọ́n òpín dé ba. 27 sùgbọ́n kò sí ẹni tí o lé wọ ilé alágbára okùnrin lọ kí ó sì kó lí ẹrù lọ láì kọ́kọ́ de okùnrin alágbára naa, lẹ́yìn na a sì ko lí ẹrù lọ. 28 Lootọ ni mo wí fun yín, gbogbo ẹ̀sẹ̀ àwọn ọmọ ènìyàn li ó ní ìdáríjì ati àwọn ọ̀rọ̀ òdì tí wọ́n sọ jáde, 29 sùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí o bá sọ̀rọ̀ òdì tako ẹ̀mí mímọ́ ki yíò ri ìdáríjì gba lailai sùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀sẹ̀ ayérayé 30 Jésù sọ ǹkan yí nítorípé wọ́n sọ pé "Ó ní ẹ̀mí aìmọ́" 31 Léyìn èyí ìyá rẹ ati àwọn arákùnrin rẹ wa, wọ́n dúró lóde. Wón sì rańsẹ́ si pe ki o wa lẹ́sẹ̀kesè. 32 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn si jókòó yi ka, wọ́n sì sọ fun wípé, "Ìyá rẹ ati àwọn arákùnrin rẹ dúró li òde, wọ́n wá ọ́ kiri " 33 Ó sì dá wọn lóhùn wípé, "ta ni ìyáà mi ati àwon arákùnkun mi?" 34 ó sì wo àwon ènìyàn tí ó jòkoó yíi ká, ó sì wípé, "Wo ìyáà mi ati àwon arákùnrin mi" 35 ẹnikẹ́ni tí ó bá se ìfé Ọlọ́run òhun ni arákùnrin mi, arábìnrin mi ati ìyá mi.