Orí Karǔn

1 Nítorínáà, ẹ se àfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́bí ọmọ ọ̀wọ́n. 2 Kí ẹ sì rìn nínú ìfẹ́, gẹ́gẹ́bí Krístì se fẹ́ wa tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún wa, crẹ òórùn dídùn àti ẹbọ fún Ọlọ́run. 3 Sùgbọ́n, kò gbọdọ̀ sí àmọ̀ràn kan nípa ìwà ìbàjẹ́ tí ìbánilòpọ̀, tàbí irúfẹ́ ìwà ìdọ̀tí tàbí ìjẹkújẹ, nítorí èyí kò tọ́ fún àwọn ènìyàn, Ọlọ́run mímọ́. 4 Kó má se sí èérí, kó má se sí ọ̀rọ̀ àlùfànsá tàbí àwọn àwàdà tí ó le - gbogbo àwọn tí kò tọ́, bíbẹ̀kọ́ ó yẹ kí á máa dúpẹ́. 5 Kí èyí kí ó dá yín lójú, kò sí alágbèrè, aláìmọ́, tàbí oníjẹkújẹ kan - tí í se abọ̀rìsà - tí yóò ní ìpín kan ní ìjọba Krístì àti ti Ọlọ́run. 6 Kí ẹnikẹ́ni máse tàn yín jẹ pẹ̀lú ọọ̀rọ̀ kòròfo nítorí nkan wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run se ḿbọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọràn. 7 Nítorínáà ẹ mase darapọ̀ mọ́ wọn. 8 Nítorí ní ìgbàkan rí òkùnkùn ni yín, sùgbọ́n nísinsìnyí, ìmọ́lẹ̀ ni yín nínú Olúwa. Ẹ rìn gẹ́gẹ́bí ọmọ ìmọ́lẹ̀. ní yín, sùgbọ́n nísinsìnyí 9 (Nítorí èso ìmọ́lẹ̀ kún fún ìserere, òdodo, àti òtítọ́). 10 Kí ẹ sì máa wádì ohun tí ó wu Olúwa. 11 Ẹ máse darapọ̀ mọ́ àíleso isẹ́ òkùnkùn, sùgbọ́n ẹ kúkú máa se àfihàn wọn. 12 Nítorí ohun itìjú ni láti máa dárúkọ ohun tí wọ́n ńse ní ìkọ̀kọ̀. 13 Sùgbọ́n nígbàtí ìmọ́lẹ̀ bá tàn, á fi ìríran hàn. 14 Nítorí´ ohun tí ó bá hàn ni ìmọ́lẹ̀. Nítorínáà ó wípé: "Jí ìwọ Olóorun, kí o sì dìde láàrin àwọn òkú, Krístì yóò tàn sí ọ. 15 Ẹ se àkíyèsí bí ẹ se ń gbé igbé ayé yín - kìí se gẹ́gẹ́bí àwọn aláìgbọ́n sùgbọ́n bí ọlọgbọ́n, 16 Ẹ ra ìgbà padà nítorí búburú ni àwọn ọjọ́. 17 Nítorínáà, ẹ máse se òmùgọ̀, sùgbọ́n ẹ ní òye ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́. 18 Ẹ má sì se fi ara yín fún ọtí mímu, nítorí èyí á mú kí ènìyàn si ìwà hù, sùgbọ́n ẹ kúkú máa kún fún Ẹ̀mímímọ́. 19 Kí ẹ má bá ara yín sọ̀rọ̀ pẹ̀lú orin Psáàlmù àti àwọn orin, àti orin ẹ̀mi, kí ẹ máa kọ́ orin nínú ẹ̀mí sí Olúwa láti inú ọkàn yín wá. 20 Ẹ máa dúpẹ́ fún ohun gbogbo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Krístì sí Ọlọ́run Baba náà. 21 Ẹ máa tẹríba fún ara yín pẹ̀lu ọ̀wọ̀ fún Krístì. 22 Ẹ̀yin aya ẹ jọ̀wọ́ ara yín fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́bí fún Olúwa. 23 Nítorí ọkọ ní íse orí aya gẹ́gẹ́bí Krístì pẹ̀lú se jẹ́ orí fún ìjọ àti Krístì fúnrarẹ̀ ni Olùgbàlà ìjọ. 24 Gẹ́gẹ́bí ìjọ se jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún Krístì bẹ́ẹ̀ pẹ̀lu àwọn aya gbọ́dọ̀ jọ̀wọ́ ara wọn fún àwọn ọkọ wọn nínú ohun gbogbo. 25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ran àwọn aya yín, gẹ́gẹ́bí Krístì ti se fẹ́ràn ìjọ tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún un. 26 Krístì jọ̀wọ́ ara Rẹ̀ fún ìjọ, kí ó ba lee sọọ́ dí mímọ́ lẹ́yìn tí ó ti sọọ́ di mímọ́ nípa íifi omi wẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀, 27 Kí ó baà le fii fún ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìjọ tí´ ó lógo láìní àbàwọ́n tàbí ìdọ̀tí tàbí irú nkan báwonnì, sùgbọ́n mímọ́ láìní àbùkù. 28 Bákannáà àwọn ọkọ yẹ kí wọ́n fẹ́ràn àwọn aya wọn gẹ́gẹ́bí ara àwọn tìkárawọn. 29 Nítorí kò sí ẹnití ó jẹ́ kórira ara òun tìkárarẹ̀, bíkòse kí ó máa kẹ́ẹ, àti se ìtọ́jú rẹ̀, gẹ́gẹ́bí Krístì se ń kẹ́ ìjọ tí ó sì n tọ́jú rẹ̀. 30 Nítorí ẹ̀yà ara Rẹ̀ ni àwa. 31 "Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi Baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì darapọ̀ mọ́ ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèjì yóò sì di ara kan." 32 Òtítọ́ tí ó pamọ́ yìí (jẹ́ èyí tí ó) ga - sùgbọ́n èmi ń sọ nípa Krístì àti ìjọ. 33 Síbẹ̀síbẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín pẹ̀lú gbọ́dọ̀ fẹ́ràn ìyàwó rẹ̀, gẹ́gẹ́bí ara òun tìkárarẹ̀, àti wípé ìyàwó náà gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.