Orí Kẹfà

1 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbọ́ràn sí àwọn òbí yín nínú Olúwa, nítorí èyí yẹ. 2 "Bọ̀wọ̀ fún Bàbá àtí ìyá rẹ" (èyí ni òfin kinní pẹ̀lú ìlérí). 3 "Kí ó lè dára fún yín, kí ẹ sì leè ní ẹ̀mí gígùn nínú ayé." 4 Ẹ̀yin Baba, ẹ máse mú àwọn ọmọ yín bínú, sùgbọ́n, ẹ tọ́ wọn nínú àsẹ Olúwa. 5 Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ gbọ́ràn sí àwọn ọ̀gá yín nínú ayé pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tí jinlẹ̀ àti ìwárìrì, nínú òtítọ́ ọkàn yín, Ẹ gbọ́ràn sí won bí ẹ ó se gbọ́ràn sí Krístì. 6 .Ẹ gbọ́ràn, kìí se nígbàtí ọ̀gá ń wò yín, kí ẹ ba leè mú inú wọn dùn, bíkòse pé kí ẹ gbọ́ràn bí ọmọ ọ̀dọ̀ Krístì, tí ó ń se ìfẹ́ Ọlọ́run láti inú ọkàn rẹ̀. 7 Ẹ se isẹ́ yín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, gẹ́gẹ́bí ẹnití ń sisẹ́ fún Olúwa tí kìí sì se ènìyàn. 8 Nítorí àwa mọ̀ pé ohun rere kóhun rere tí ẹnìkọ̀ọ̀kan bá se, yóò gbà èrè lọ́wọ́ Olúwa, ìbá se ẹrú tàbí òmìnira. 9 Ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ tọ́jú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ bákannáà. Ẹ máse halẹ̀ mọ́ won. Ẹ kúkú mọ̀ wípé ọ̀gá ẹ̀yin méjèjì wà ní ọ̀run, kò sì sí ojúsàájú pẹ̀lú Rẹ̀ 10 Ní àkótán ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa àti nínú agbára ipá Rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhàmọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin kí ó leè dúró láti dojúkọ àrèkérekè èètò ti èsù. 12 Nítorí kìí se ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ ni àwa ḿbá jìjàdadì, bíkòse àwọn ìjọba, àwọn alásẹ, àti àwọn alákòso ẹ̀mí nínú òkùnkùn, àti àwọn ẹ̀mí búburú nínú àwọn ọ̀run. 13 Nítorínáà, ẹ gbé gbogbo ìhàmọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin kí ó leè dúró nínú àkókò ibi yìí, àti lẹ́yìn tí ẹ bá ti se ohun gbogbo tán, láti dúró gírí. 14 Ẹ dúró, nítorínáà, lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá ti fi ọ̀já ìgbànú ti òtítọ́ àti ìgbayà tí òdodo nì mọ́ ara. 15 Bẹ́ẹ̀ni bàtà fún ẹsẹ̀ yín, ẹ gbé ìmúra tó setán láti polungo ìyìnrere ti àláìia wọ̀. 16 Ní gbogbo ohunkóhun ẹ mú apata ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin yóò fi leè pa iná àwọn ọfà ẹni ibi nì. 17 Ẹ sì mú akoto ìgbàlà àti idà ẹ̀mí, tíí se ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 18 Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ìsìpẹ̀, ẹ gbadúrà ní ìgbà gbogbo nínú Ẹ̀mí. Pẹ̀lú ọkàn yìí, ẹ má sọ́nà ní ìgbà gbogbo pẹ̀lú ìpamọ́ra gbogbo, gẹ́gẹ́bí ẹ se ń gbàdúrà fún gbogbo àwọn ènìyàn, Ọlọ́run, mímọ́ 19 Kí ẹ sì gbàdúrà fún mi, pé kí á leè fún mi ní isẹ́ ìránsẹ́ kan nígbàtí mo bá ya ẹnu mi. Ẹ gbàdúrà pé kí n leè ma sọọ́ di mímọ̀ pẹ̀lú ìgboyà àwọn òtítọ́ náà tí ó pamọ́ nípa ìyìnrere. 20 Nítorí ìyìnrere ni mo se di ikọ̀ tí a pamọ́ nínú ìdè, kí n leè máa sọọ́ pẹ̀lú ìgboyà, gẹ́gẹ́bí ó se yẹ kí n sọ̀rọ̀. 21 Tíkíkù, arákùnrin olùfẹ́, àti ìránsẹ́ olòótọ́ nínú Olúwa, yóò sọ ohun gbogbo fún yín, kí ẹ̀yin kí ó leè mọ̀ bí mo se ń se. 22 Mo ti rán an sí yín nítorí ìdí èyí, kí ẹ leè mọ̀ bí a se wà, kí òun kí ó leè mú yín lọ́kàn le. 23 Àláìia fún gbogbo àwon arákùnrin, àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Olúwa Jésù Krístì. 24 Ki ore ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa Jésù Krístì pẹ̀lú ìfẹ́ tí kìí kú.