Orí Ìkẹ́rin

1 Èmi, nítorínáà, gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́wọ̀n fún Olúwa, ńrọ̀ yín láti rìn ní yíyẹ fún ìpè yín tí a fi pè yín. 2 Mo rọ̀ yín kí ẹ gbé ìgbé ayé ìrẹ̀lẹ̀ tí ó tóbi pẹ̀lú ìfarabalẹ̀ àti sùùrù, kí á máa gbé pẹ̀lú omonìkẹ̀jì wa pẹ̀lú ìfẹ́. 3 Se aápọn láti pa ìsọ̀kan ti Ẹ̀mí mọ́ níní ìdè ṣ`àláfìa. 4 Ara kan ní ḿbẹ àti Ẹ̀mí kan, gẹ́gẹ́bí a se pè yín pẹ̀lú sínú ìrètí ìpè yín. 5 Bẹ́nì Olúwa kan ní ḿbẹ, ìgbàgbọ́ kan, ìtẹ̀bọmi kan, 6 Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo gbò, tí ó ńse orí ohun gbogbo atì nípasẹ̀ ohun gbogbo nínú ohun gbogbo. 7 Fún ẹnìkọ̀kan wa ni a ti fún ní oore òfẹ́ gẹ́gẹ́bí ìwọ̀n ẹ̀bùn Krístì. 8 Gẹ́gẹ́bí ìwé mímọ́ se sọ: "Nígbàtí ó gòkè lọ sí àwọn ibi gíga, ó de ìgbèkùn ní ìgbèkùn, ó sì fi ẹ̀bùn fún ènìyàn." 9 Kí ni ìtumọ̀ wípé: "Ó gòkè," bíkòsepé ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ibi tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú ayé? 10 Ẹnití ó sọ̀kalẹ̀, ohun kanna ni ẹnití ó gòkè rékọjá àwọn ọ̀run, kí ó baà le kún ohun gbogbo . 11 Krístì fún àwọn ẹlòmíràn láti jẹ́ àpóstélì, àwọn miran wòólì, àwọn miran ajíhìnrere, àti àwọn miran olùsọ́àgùntàn àti olùkọ́ni. 12 Ó fi àwọn ẹ̀bùn isẹ́ wọ̀nyí fún ni láti dira isẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́, àti fún ìmúdàgbà ara Krístì. 13 Ó tẹ̀síwájú láti mú ìdàgbàsókè bá ara rẹ̀ títí gbogbo wa yóò fi dé ìsọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi dàgbà títí dé ìwọ̀n ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Krístì. 14 Krístì mú wa dàgbà nítorí kí á má baà se mọ̀jèsín mọ́, tí a ń fi afẹ́fẹ́ tì síwá sẹ́yìn pẹ̀lú afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ àti àrékérekè àwọn ènìyàn nínú ẹ̀tàn wọn. 15 Dípò èyí, kí á máa sọ òtítọ́ nínú ìfẹ́, a ní láti dàgbà ní gbogbo ọ̀nà nínú Rẹ̀, ẹnití íse orí, èyí ni Krístì. 16 Krístì ti kó gbogbo ara, ó sì ti soó pọ̀ nípa gbogbo ẹ̀yà ara, nígbàtí gbogbo wọn bá sisẹ́ papọ̀, èyí yóò mú kí ara dàgbà sókè nínú ìfẹ́. 17 Nítorínáà, mo wípé, mo sì tẹnumọ èyí nínú Olúwa pé: ẹ kò gbọdọ̀ gbé ìgbé ayé yín gẹ́gẹ́bí ti àwọn Kèfèrí nínú ìgbé ayé ọkàn wọn tí ó sófo 18 Òye won sókùnkùn, wọ́n se àjéjì sí ìgbé ayé tí ó wà nínú Ọlọ́run, nítorí òpè ni wọ́n nítorí ọkàn wọn sébọ́, ó sì le. 19 Wọn kò ní ìtìjú, wọ́n sì ti jọ̀wọ́ ara wọn fún ìsekúse, wọ́n sì tẹ̀síwájú láti máa se orísirísi àwọn n kan aláìmọ́. 20 Sùgbọ́n èyí kìí se ọ̀nà láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Krístì. 21 Mo lérò wípé ẹ ti gbọ́ nípa Rẹ̀, àti wípé ati fi kọ yín gẹ́gẹ́bí òtítọ́ tí ó wà nínú Jésù. 22 Ati fi kọ́ yín láti bọ́ àwọn ìwà yín àtijọ́ sílẹ̀, láti bọ́ ògbólògbó ọkùnrin àtijọ́ náà sílẹ̀. Ọkùnrin ògbólògbó tí ó bàjẹ́ nítorí ẹ̀tàn ìfẹ́kùfẹ́ rẹ̀. 23 A ti kọ́ yín láti di titun nínú ẹ̀mí ọkàn yín, 24 Àti láti gbé ọkùnrin titun náà wọ̀ tí a ti dá ní àwòrán Ọlọ́run, ní òtítọ́, òdodo àti ìwà mímọ́. 25 Nítorínáà, ẹ dágbére fún irọ́ gbogbo, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín kí ó máa sọ òtítọ́ pẹ̀lú aládùúgbò, nítorí ẹ̀yà ara kannáà ni a jẹ́ fún ara wa. 26 Ẹ bínú, ẹ má sì se sẹ̀. Ẹ máse jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú yín. 27 Ẹ máse fún èsù ní ààyè. 28 Ẹnití ó n jalè, kò gbọdọ̀ jalè mọ́. Ó gbọ́dọ̀ sisẹ́, isẹ́ tí ó wúlò pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀, kí òun pẹ̀lú kí ó lè ní ohun tí ó lè pín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí ó se aláìní. 29 Ẹ máse jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan kí ó ti ẹnu yín jáde. Ẹ máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé ni ró gẹ́gẹ́bí aìní olukúlùkù, kí ọ̀rọ̀ yín lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí ó bá ń gbọ́ yín 30 Ẹ má sì se mú Ẹ̀mímímọ́ Ọlọ́run bínú, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni a se èdìdí yín fún ọjọ́ ìràpadà. 31 Ẹ pa ìkorò, ìbínú, ìrúnú, ìjà, àti ìtẹ́mbẹ́lú ara ẹni sí apákan, pẹ̀lú ibi gbogbo. 32 Ẹ se inú rere fún ara yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ dáríjìn ará yin gẹ́gẹ́bí Ọlọ́run nínú Krístì se dáríjìn yin.