Orí Ìkẹ́ta

1 Nítorí ìdí èyí, èmi Pọ́ọ̀lù, ẹlẹ́wọ̀n Jesù Krístì ni mí fún àwọn Kèfèrí 2 Mo lérò wípé ẹ ti gbọ́ nípa ìrìjú ti ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi nítorí tiyín. 3 Mo ń kọ̀wé gẹ́gẹ́bí ìfihàn tí a mú kí n mọ̀. Èyí ni òtítọ́ tí ó pamọ́, tí mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín ní kía. 4 Nígbàtí ẹ bá ka èyí, yóò le yé yín, òye ti mo ní nípa òtítọ́ tí o pamọ́ nípa Krístì. 5 Ní àwon ìran míran, òtítọ́ yìí kò di mímọ̀ sí àwọn ọmọ ènìyaàn. Sùgbọ́n nísinsìnyí, ó ti di fífihàn nípa Ẹ̀mí sí àwọn àpòstélì àti wòólì tí a yà sọ́tọ̀ fún isẹ́ yìí. 6 Òtítọ́ tí ó pamọ́ yìí ni wípé, àwọn kèfèrí pẹ̀lú àwọn ajogún àti àwọn akẹgbẹ́, àti pé wọ́n pín nínú ìlèrí tí ó wà nínú Krístì Jésù nípa ti ìhìnrere náà. 7 Nítorí mo di ìránsẹ́ ìhìnrere nípa ẹ̀bùn ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi nípa isẹ́ agbára Rẹ̀. 8 Ọlọ́run fún mí ní ẹ̀bùn yìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ó kéré jù nínú àwon ènìyàn, Ọlọ́run, mímọ́. Ẹ̀bùn yìí ni wípé, mo gbọ́dọ̀ kéde ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ìhìnrere Krístì sí àwon Kèfèrí. 9 Ẹ̀bùn Ọlọ́run fún mi ní wípé n gó mú ẹnìkọ̀kan wá sínú ìmọ́lẹ̀ ohun tí ète Ọlọ́run jẹ́. Ète yìí tí wà nínú ìpamọ́ láti aìmoye ọdún sẹ́yìn nípa Ọlọ́run tí ó dá ohun gbogbo. 10 Ète yìí ni a sọ di mímọ̀ nipaseẹ̀ ìjọ, kí àwọn ìjoba àti alásẹ ní àwọn ọ̀run leè mọ̀ irúfẹ́ ìsẹ̀dá ọgbọ́n Ọlọ́run. 11 Èyí sẹlẹ̀ gẹ́gẹ́bí ète ayérayé tí ó di mímúse nínú Krístì Jésù Olúwa wa. 12 Nítorí nínú Krístì a ní ìgboyà àti ọ̀nà pẹ̀lú ìkiniláyà nítorí ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀, 13 Nítorínáà, mo béèrè wípé kí ẹ máse rẹ̀wẹ̀sì nítorí, ohun tí mo ńjìyà fún yín, èyí tí íse ògo yín. 14 Nítorí ìdí èyí, mo wà lórí orúnkún mi sí Baba. 15 Láti ọ̀dọ̀ ẹnití a ti sọ gbogbo ìdílé ní Ọ̀run àti ní aye ní orúkọ. 16 Mo gbàdúrà pé kí O fifún yín gẹ́gẹ́bí ọrọ̀ ògo Rẹ̀, kí ó fún yín ní okun pẹ̀lú agbára nípa Ẹ̀mí Rẹ̀ tí ó wà nínú yín. 17 Mo gbàdúrà kí Krístì lè gbé nínú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́, pé kí ẹ lè ta gbòngbò mọ́lẹ̀, kí á sì gún yín kúnná nínú ìfẹ́. 18 Kí ó fún yín ní ọkun, kí òye kí ó leè yé yín pẹ̀lú gbogbo àwọn onígbàgbọ́, kí ni fífẹ̀, gígùn, gíga, àti jíjìn 19 Àti pé kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ ìfẹ́ Krístì tí ó tayọ ìmọ̀, àti wípé kí á lè fún yín pẹ̀lú gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run. 20 Ǹjẹ́ nísinsìnyí, sí ẹnití ó lè se gidigidi ju ohun gbogbo tí a nbéèrè, tàbí tí a ń rò, gẹ́gẹ́bí agbára tí ó ńsisẹ́ nínú wa 21 Ohun ni ògo wà fún nínú ìjọ àti nínú Krístì Jésù sí gbogbo ìrandíra laí àti laílaí, àmín.