Orí Kejì

1 Nísinsìnyí nípa wíwá Olúwa wa Jésù Kristì àti ìpéjọpọ̀ wa láti wà pẹ̀lú Rẹ̀: a bẹ̀ yín, ará, 2 pé kí ẹ̀yín kí ó má tètè dààmú tàbí pòrúrú ọkàn, bóyá nípa ti ẹ̀mí, ìwásù, tàbí nípa ìwé bìi láti ọ̀dọ̀ wa wá, fún pé ọjọ́ Olúwa ti dé ná. 3 Ẹ máse jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ lọ́nàkọnà. Nítorípé kí yóò wá bíkòsepé ọjọ́ ìyapa bá dé, tí a ó sì fi ẹlẹ́ṣẹ̀ náà hàn, ọmọ ìparun. 4 Òun ni ẹni tí ń lòdì tí ó sì ń gbé ara rẹ̀ ga sí ohungbogbo tí à ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí à ń sìn. Ní àbáyọrí pé, ó jòkó nínú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ó sì tún fi ara rẹ̀ han pé Ọlọ́run ni Òun. 5 Ẹ̀yin kò rántí pé nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín mo sọ nǹkan wọ̀nyìí? 6 Nísinsìnyí ẹ̀yín mọ ohun tí ó ń se ìdènà, pé kí á le fihàn ní àkókò tí ó tọ́ nìkan. 7 Nítorí ohun ìjìnlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́, kìki pé ẹnìkan wà tí ó ń se ìdènà fun nísinsìnyí títí a ó fi mu kúrò lọ́nà. 8 Nígbànáà ni a ó fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ náà hàn, ẹnití Jésù Olúwa yóò fi èémí ẹnu rẹ̀ pá. Olúwa yóò mu wá sí asán nípa ìfihàn bíbọ̀ ọ rẹ̀. 9 Ọkùnrin ẹni ẹ̀ṣẹ ẹ̀ nì tí yóò wá nítorí iṣẹ́ sátánì pẹ̀lú gbogbo agbára, àmìn, àti èké iṣẹ́ gbogbo, 10 àti pẹ̀lú gbogbo ìtànjẹ àìsòdodo. Nǹkan wọ̀nyí yóò wà fún àwọn tí ń sègbé, nítorí tí wọn kò gba ìfẹ́ òtítọ́ tí ó wà fún ìgbàlà wọn. 11 Fún ìdí èyí, Ọlọ́run rán iṣẹ́ ìṣìnà sí wọn kí wọn le gba èké gbọ́. 12 Àbáyọrí rẹ̀ ni wípé pé a ó se ìdájọ́ gbogbo wọn, àwọn tí wọn ò gba òtítọ́ ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú dídùn sí àìsòdodo. 13 Ṣùgbọ́n ó yẹ kí á sábà máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí, ẹ̀yin arákùnrin tí olúwa fẹ́. Nítorí Ọlọ́run yànyín sí èso àkọ́soní ìsọdimímọ́ àti ìgbàlà nínú Ẹ̀mí àti ìgbàgbọ́ nínú òtítọ́. 14 Èyí ni ohun tí ò pè yín fún pé nípa ìhìnrere wa láti le gba ògo ti Jésù kristì Olúwa wa. 15 Nítorínáà, ará, ẹ dúró sinsin. Kí ẹ sì dì ẹ̀kọ́ tí a ti kọ yín mú sinsin, bóyá nípa ọ̀rọ̀ tàbí ìwe wa tí a kọ si yín. 16 Nísinsìnyí kí Olúwa wa Jésù Kristì fún ra rẹ̀, àti Ọlọ́run Bàbá wa tí ó fẹ́ wa tí ó sì tún fún wa ní ìtùnú ayérayé àti ìgboyà rere fún ọjọ́ ìkẹyìn nípa ore-ọ̀fẹ́, 17 ìtùnú, kí ó fi ẹṣẹ̀ yín múlẹ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ rere àti ọ̀rọ̀.