Orí Kẹta

1 Nísinsìnyí ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa pé kí ọ̀rọ̀ Ọlórun tàn jáde ní kánkán kí ó si di ṣíse lògo, gẹ́gẹ́ bí ó tise wà láàrin yín. 2 Ẹ máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run gbàwá lọ́wọ̀ àwọn ìkà àti àwọn ènìyàn búburú, nítorí kìí ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó gbàgbọ́. 3 Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, Òhun yóò fi ẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀, yóò sì gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú. 4 A ní ìgboyà nínú Olúwa nípa yín pé, ẹ̀yin ńṣe, àti pé ẹ̀yin yóò sì tún tẹ̀síwájú láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti paá láṣẹ fun yin. 5 Ǹjẹ́, kí Olúwa darí ọkàn yín sí Ìfẹ́ ti Ọlọ́run àti sí ìfaradà ti Krístì. 6 Ǹjẹ́, ará, ní orúkọ Olúwa wa Jésù Krístì, apaá lásẹ fún yín pé, kí ẹ yàgò fún àwọn ará tí ó n se ìmẹ́lẹ́ àti tí wọn kò rìn ní ìbamu pẹ̀lú ìlànà tí ẹti gbà láti ọ̀dọ wa. 7 Nítorí ẹ̀yin tìkarayín mọ̀ pe ohun tí ó tọ̀nà ni fún yín láti máa wo àwòkóse wa. Nítorí àwa kò gbé làárín yín bíi ẹnití kò lẹ́kọ̀ọ́. 8 Àwa kò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni láì san owó. Dípò èyí, àwá ṣisẹ́ ní ọ̀sán àti ní òru pẹ̀lú agbárakáká, làálàá ati aápọn, kí àwá má baà jẹ́ àjàgà fún yín. 9 Àwa ṣìṣe èyí láti jẹ́ àpẹre rere fún yín àti pé, ki ẹ̀yin le tẹ̀lé àwòkọ́ṣe wa, kìí ṣepé àwa kòní àṣẹ. 10 Nígbàtí a wà pẹ̀lú yín, a paá láṣe fún yín pé, tí ẹnikẹ́ni kò bá fé ṣiṣẹ́ kò gbọdọ̀ jẹun. 11 Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ńṣe ìmẹ́lẹ́ làárín yín, wọn kò ṣiṣẹ́ ṣùgbón dípò wọn ń fínràn. 12 Nísinsiǹyí, irúfẹ́ àwọn ènìyán yí ni a paá láṣẹ tí asìgbà níyáǹjú nínú Olúwa pé, kí wọ́n máa ṣisẹ ní ìdákẹ́rọ́rọ́ àti pé kí wọ́n máa je nínú oúnje ara won. 13 Ẹ má ṣe jẹ́kí ọkàn yín fà kúrò nínú ṣíse ohun tí ó tọ́. 14 Bí ẹnikéni kò bá gba ọ̀rọ̀ tí a kọ sínú ìwé yìí gbọ́, ẹ kíyèsí rẹ̀, kí ẹ má sìṣe ní ohun kankan ṣe pèlú rẹ̀, kí ojú leè tìí. 15 Máṣe ríì gẹ́gẹ́ bi ọ̀tá, ṣùgbọ́n kì í nílọ̀ bí arákùnrin rẹ. 16 Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run àláfíà fún yín ní àláfíà ní gbogbo ọ̀nà àti ní gbogbo ìgbà. Kí Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín. 17 Èyí ni ìkini, láti ọwọ́ pọ́ọ̀lù wá, tíí se àmì nínú àwọn ìwé tí mo kọ. Èyí ni bí Moṣe ń kọ̀wé. 18 Ǹjẹ́, kí ore ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jésù krístì wà pèlú yín. Àmín