1
Pọ́ọ̀lù, Sílfánù, àti Tìmótíù, sí ìjọ Tẹsalóníkà nínú Ọlọ́run Bàbá wa àti Olúwa Jésù Kristì.
2
Kí ore-ọ̀fẹ́ àti àláfíà jẹ́ ti yín láti ọ̀dọ Olọ́run Bàbá wa àti Olúwa Jésù Kristì.
3
A gbọdọ̀ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nígbàgbogbo fún yín, ará. Nítorí èyí ni ó tọ̀nà, nítorípé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà púpọ̀púpọ̀ àti ìfẹ́ olúkúlùkù sí ara wọn ń pọ̀si.
4
Nítorí náà ni àwa tìkarawa fi ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà nípa yín láàrin ìjọ Ọlọ́run. À ń sọ̀rọ̀ sùúrù àti ìgbàgbọ́ nínú gbogbo inúnibíni yín. À ń sọ̀rọ̀ nípa wàhálà tí ẹ faradà.
5
Èyí ni àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. Ère rẹ̀ ni pé a ó kà yín yẹ ní ìjọba Ọlọ́run nínú èyí tí ẹ jìyà lé lórí.
6
Òdodo ni fún Ọlọ́run láti dá ìpọ́njú padà sì ọ̀dọ̀ àwọn tí ó ń pọ̀n yín lójú,
7
Àti ìtura fún ẹ̀yin tí a pọ́n lójú pẹ̀lú wa. Yóò se èyí nígbà ìfarahàn Jésù Olúwa láti Ọrun wá pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì alágbára Rẹ̀.
8
Nínú ọ̀wọ́ iná ni yóò gba ẹ̀san lára àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò gba ìhìnrere Jésù Olúwa wa.
9
Wọn ó jìyà ìparun kúro níwájú Olúwa wa àti nínú ògo agbára Rẹ̀.
10
Yóò se èyí nígbà tí ó bá dé ní ọjọ́ náà kí àwọn ènìyàn Rẹ̀ le se é lógo. Nítorí a gba ẹ̀rí wa fun yín gbọ́.
11
Nítorí eyi à ń gbàdúrà nígbàgbogbo fun yín. À gbàdúrà pé Ọlọ́run wa yóò kà yín yẹ fún ìpè yín. Àti pé kí ó le mú gbogbo èrò rere àti gbogbo iṣẹ́ ìgbàgbọ́ ṣẹ pẹ̀lú agbára.
12
A gbàdúrà nǹkan wọ̀nyìí kí orúkọ Jésù Olúwa wa le è di gbígbéga nípa yín. A gbàdúrà pé kí ẹ di ẹni íse lógo nípa Rẹ̀, nítorí ore-ọ́fẹ́ Ọlọ́run wa àti Olúwa wa Jésu Kristì.