Orín Kaàrún

1 Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí. Dípò, gbàá níyànjú gẹ́gẹ́ bíi bàbá. Gba àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin níyànjú gẹ́gẹ́ bíi arákùnrin. 2 Gba àwọn àgbàlagbà obìnrin níyànjú gẹ́gẹ́ bi màmá, àti àwọn ọ̀dọ́mobìnrin gẹ́gẹ́ bíi arábìnrin pẹ̀lú ìwà mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà. 3 Bu ọlá fún àwọn opó, àwọn opó tòótọ́. 4 Ṣùgbọ́n tí opó bá ní àwọn ọmọ tàbí ọmọ-ọmọ, jẹ́ kí wọ́n ó kọ́kọ́ kọ́ bí a tí ń fi ọlá hàn nínú ilé ara wọn. Jẹ́kí wọ́n ó san fún àwọn òbí wọn, nítorí èyí tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. 5 Ṣùgbọ́n opó tòótọ́ wà láì ní ẹnìkankan. Ó fi ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ rẹ̀ sínú Ọlọ́run. Óún wá pẹ̀lú ìbéèrè àti àdúrà ní gbogbo ìgbá, lóru àti lọ́sàn. 6 Ṣúgbọ̀n, obìnrin tí ń bá ńgbé fún afẹ́ àti ìfẹ́kùfẹ́ ti dòkú bí ótilẹ̀ jọpé ó wà láàyè. 7 Wàásù àwọn ǹkan wọ̀nyí kí wọ́n baà le wà láì lẹ́bi. 8 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún ilé rẹ̀, pàápajàlo àwọn tí ó jẹ́ ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́ èyí sì burú jáì ju aláìgbàgbọ́ lọ. 9 opóbìnrin fi orúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí opó níwọ̀n ìgbà tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá tì pé ọgọ́ta, tí ó jẹ́ aya ọlọ́kọ kan. 10 A gbọ̀dọ̀ mọ̀ ó fún iṣọ́ rere, yálà òún ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọdé tàbí ìgbàlejò àwọn àjòjì, tàbí ó ti farahìn fún iṣẹ́ rere gbogbo. 11 fún opó kékeré, ẹ kọ̀ láti fi orúkọ rẹ̀ sílẹ̀. Ńítorí nígbà tí wọn kò si lè máradúró lòdì sí Krístì, wọ́n fẹ́ láti lọ́kọ. 12 Ní ọ̀nà yí won yóo gba ìdálẹ́bi nítorí wọ́n ti kọ ìfarajìn àkọ́kọ́ wọn sílẹ̀. 13 Wọ́n sì sábà má ń wà lálàì níṣẹ́. Wọ́n á maa lọ kákàkiri sí ilé sí ilé. Kìí sì ṣepé wọn kò níṣẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n ó di ẹni tí n sọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ àti alátòjubọ́. Wọ́n ó máa sọ ohun tí kò yẹ kí wọ́n ó sọ. 14 Nítorínà mo fẹ́ kí àwọn opó kékèké kí ó lọ́kọ, kí wọ́n ó bímọ, kí wọ́n ó tọ́jú ilé, láti má fi àyè sílẹ̀ fún alátakò láti takò wá nípa ṣíṣe ibi. 15 Nítorí àwọn kan ti yà kúrò wọ́n sì tẹ̀lẹ́ sátáni. 16 Bí obìnrin onígbàgbọ́ kan bá ní àwọn opó, jẹ́ kó rànwọ́lọ́wọ́, kí ọrún má baà wọ ìjọ, kí ìjọ ba lè ran àwọn opó tòótọ́ lọ́wọ́. 17 Ẹbu olá ńlá fún àwọn àgba tí ń ṣe ìdarí dáradára, pàápàá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nínú ìkọ́ni. 18 Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọpé "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ so enu màálù tín te oká," àti wípé "Alágbàṣe yẹ fún èrè rẹ̀. 19 Má ṣe gba ìfisùn lòdì sí àgbàlagbà bí kòṣe láti enu ẹlẹ́rǐ méjì sí mẹ́ta. 20 Bá ẹlẹ́ṣẹ̀ wí ní gbangba kí àwọn ìyókù balè bẹ̀rù. 21 Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni mo páá láṣẹ fún o níwájú Ọlọ́run àti níwájú Krístì Jésù àti àwọn ángẹ́lì wọn tí ayàn, wípé kí ó pa àwọn òfin yìí mọ́ láì sí ìkòrira àti kí o sì ṣe ohun gbogbo láì sí ojúṣàájú. 22 Má ṣe yára láti gbọ́wọ́ lé ẹnikẹ́ni. Má ṣe pín nínú ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn. Ó ye kí o máa pa ara rẹ́ mọ́. 23 Má se mu omi nìkan mọ́. Dípò máa mu wáìnì díẹ̀ fún ikùn rẹ àti fún àwọn àìsàn òrèkóòrè rẹ. 24 Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn kan jẹ́ èyí tó farahàn, tí wọ́n sì ń ṣíwájú wọn lọ sí ìdájọ́. Ṣùgbọn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kán ń tẹ̀lé wọn tó báyá. 25 Bákańnà, àwo.n iṣẹ́ rere kan farahàn, ṣùgbọ́n kódà àwọn èyí tókù náà kò ní farapamọ́.