Orí Kẹfà

1 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tó wà nínú àjàgà ẹrú rǏ olúwa wọn gẹ́gẹ́ bi ẹni tó yẹ fún ìyìn. Kí wọ́n ṣe èyí kí orúkọ Ọlọ́run àti ìkónni má ṣe di sí sọ̀rọ̀ òdì sì. 2 Àwọn erú tó ní olúwa tí ó gbàgbọ́ kò gbọdọ̀ rí wọ́n fín nítorí wọ́n jẹ́ arákùnrin wọn. Dípò, kí wọ́n tún bọ̀ máa sìn wọ́n síi. Nítorí àwọn olúwa tí a rànlánwọ́ nípa iṣẹ́ wọn jé onígbàgbọ́ àti ẹni ìfẹ́. Kó í o sì sọ àwọn ǹkan wọ̀nyi. 3 Bí ẹnikẹ́ni bá n kọ́ ni nì ẹ̀kọ́ ọ̀tọ̀ tí kò si gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ wa, èyí nì, ọ̀rọ̀ Ọlúwa wa Jésù Kristì. Bí wọ́n kò bá gba ẹ̀kọ́ tó n yọrísí ìwà-bí-Ọlórun. 4 Ẹni na jẹ́ onígbéraga àti aláimọ̀kan. Dípò, ó ní àìsàn pèlú àríyànjiyàn àti ìjìyàn nípa ọ̀rọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ yi já sí ìlara, ìjà, ẹ̀gàn, ìfura ibi àti 5 rògbòdìyàn gbogbo ìgbà lárìín àwọn èyàn pèlú ọ̀kàn ibi. Wọ́n lòdì sí òtítọ́. Wọ́n rò wípé ìwà-bí-Ọlórun jé ọ̀na láti di ọlọ́rọ̀. 6 Nísisìyí, ìwà-bí-Ọlọ́run pèlú ìtẹ́lọ́rùn jé èrè nlá. 7 Nítorí à kò mú ohunkóhun wá sí ayé. Bẹ́ẹ̀ni a kò ní le mú ohunkóhun lọ. 8 Dípò, ẹ jé kí á ní ìtẹ́lọ́rùn pèlú óunjẹ àti aṣọ. 9 Nísisìyí àwọn tó fẹ́ di ọlọ́rọ̀ ṣubú sínú ìdánwò, sínu pàkúté. Wọ́n ṣubú sínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òmùgò àti ìfẹ́kúfẹ̌ tí ó ń panilára, àti ohunkóhun tó má ń mú àwọn ènìyàn rì sínú ìparun àti ègbé. 10 Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburù gbogbo. Âwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̌ rẹ̀ ti ṣìnà kúrò nínu ìgbàgbọ́ wọ́n sì ti gún ara wọn pèlú ìbìnújé tó pọ̀. 11 Ṣùgbọ́n ìwọ, ènìyàn Ọlórun, sá kúrò fún àwọn ǹkan wọ̀nyí. Lépa òdodo, ìwà bí Ọlórun, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, àti ìwà tútù. 12 Jà ìjà tì ìgbàgbọ́. Di ìyè ayérayé èyí tí à pè ó sí mú. Nípa èyí ni o jẹ́ ẹ̀rí níwájú àwọn ẹlẹ́rìí nípa ǹkan tó dára. 13 Mo fún yín ní àwọn òfin yì níwájú Ọlọ́run, tí ó sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Kristì Jésù, tí ó sọ òtítọ́ sí Póintù Pílátù: 14 pa òfin mọ́ dáradára, láìsí ẹ̀gaǹ, títí di ìfarahán Ọlúwa wa Jésù Kristì. 15 Ọlórun yó fi ara Rẹ̀ hàn ni àsìkò tó tọ́--- Ọlórun, Olùbùkún nì, Agbára kan soso, Ọba tó jọba, Olúwa tó darí. 16 Òun nìkan ló jẹ́ àìkú tó sin gbé nínú ìmólẹ̀ tí a kò le è sún mọ́. Ènìyàn kankan kò ri tàbí le wòó. Fún òun ni ìyìn àti agbára ayérayé. Àmín 17 Ẹ sọ fún àwọn olówo ayé kí wọ́n má ṣe gbéraga, kí wọ́n má ṣe ní ìrètí nínú ọ̀rọ̀, tí kò dájú. Dípò, kí wọ́n ní ìrètí nínú Ọlórun. Ó pèsè ọrọ̀ òtítọ́ fún wa láti le gbádùn. 18 Sọ fún wọn kí wọ́n má a se oore, kí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú iṣẹ́ dáradàra, láti jẹ́ onínúrere, àti láti ṣe tán láti pín. 19 Ní ọ̀nà náà, wọ́n yó to ìpìnlẹ̀ dáradára fún ara wọn fún èyí tí ó ń bọ̀, ki wọ́n lè di ìyè òtítọ́ mu. 20 Tímótìù, pa ǹkan tí a fí fun ọ mọ́. Yàgò fún ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ àti àríyànjiyàn tí o lòdì nípa nǹkan tí à ń fi èké pè ní ìmọ̀. 21 Àwọn ènìyàn kan kéde àwọn ǹkan wọ̀nyi wọ́n sì ti sìnà ìgbàgbọ́. Kí oreọ̀fẹ́ ó wà pèlù yín.