Orí Kẹrin

1 Nísinsìnyí Ẹ̀mí ń ké tantan wípé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn ènìyàn kan yóó fi ìgbàgbọ́ sílẹ̀, wọ́n yóò sì fi iyè sí àwọn ẹni ẹ̀tàn àti ìkọ́ni àwọn démónì. 2 Nínú àgàbàgebè irò. Ẹ̀rí ọkàn wọn yóó di ti sàtánì. 5 3 Wọ́n ó kọ̀ láti ṣe ìgbéyàwó àti láti gba óúnjẹ ti Ọlọ́run dá fún pínpín pẹ̀lú ọpẹ́ láàrín àwọn tí ó gbàgbọ́ tí ó sì mọ òtítọ́. 4 Nítorí gbogbo oun tí Ọlọ́run dá dáradára ni. kò sí oun tí a gbà pẹ̀ú ọpẹ́ tí ó gbọdọ̀ di kíkọ̀. 5 Nítorí ati yàá sí mímọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà. 6 Ìwọ yóó jẹ́ ìránṣẹ́ Jésù Kristì tí ó dára tí ìwọ bá gbé gbogbo àwọn ǹkan wọ̀nyí síwaju àwọn ará. Nítorí à ńbọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òrò ìgbàgbọ́ àti pẹ̀lú ìkọ́ni tí ó yè koro tí ó ti tẹ̀lé. 7 Ṣùgbọ́n kọ gbògbo àwọn àlọ́ àti ìtàn tí kò wúlò. Nípò rẹ̀, kọ́ arà rẹ ní ìwà bí Ọlọ́run. 8 Ìwúlò eré ìdárayá díè ni, ṣùgbọ́n ìwà bíi Ọlọ́run wúlò fún ohun gbogbo. Óní èrè fún ayé yìí nísinsìnyí àti fún ayé èyí tó ńbọ̀. 9 Òdodo ni ọ̀rọ̀ yí, ó sì yẹ fùn ìtẹ́wọ́gbà tokàntokàn. 10 Nítorí fún èyí ni àwa sì ń ṣiṣẹ́ kárakára. Nítorí àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run alààyè, eni tí ń ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyan, pàápáà jùlọ àwọn onígbàgbọ́. 11 Máa kéde kí o sì máà kọ́ àwọn ǹkan wọnyi. 12 Má ṣe jé kí ẹnikọ́ni gan jíjẹ́ ọ̀dọ́ rẹ. Dípò, jẹ́ àpẹ̀ẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀, ìṣe, ìfẹ́, òtítọ́ àti ìwà mímọ́. 13 Títí tí n ó fi dé, tẹ̀ síwájú láti máa ṣe kíkà, àlàyé àti ìkọ́ni Ọlọ́run. 14 Má ṣe pa àwọn ẹ̀bùn tí ń bẹ nínú rẹ ti èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ìgbọ́wọ́ léni lórí àwọn àgbà. Má se àníyàn àwọn ǹkan wọ̀nyi. Ma gbé nínú wọn, kí ìtẹ̀síwájú rẹ lee farahàn fún gbogbo ènìyàn. 15 Fi pẹ̀lẹ́pèlẹ́ kíyèsi arà rẹ àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Tẹ̀síwájú nínú àwọn ǹkan wọ̀nyí. 16 Nítorí nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóó gba ara rẹ là àti àwọn tí ń tẹ́tí gbọ́ ọ.