Orí Kẹta

1 Ọ̀rọ̀ yí gbọdọ̀ jẹ̀ òtítọ́: Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti jẹ́ alámòjútó, oun fẹ́ isẹ́ rere. 2 Nítorínà alámòjútó gbọdọ̀ wà láì lẹ́bi. Ó gbọdọ̀ jẹ̀ ọkọ aláya kan. Ó gbọdọ̀ jẹ̀ oníwọ̀ntunwọ̀nsì, olórí pípé, omolúàbí, ẹni tí ń se àlejò. Ó gbọdọ̀ leè kọ́ ni. 3 Kò gbọdọ̀ jẹ̀ ọ̀mùtí para, oníjà, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ àti alálàáfíà. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tó fẹ́ràn owó. 4 Ó gbọdọ̀ bójútó inú ile rẹ̀ dáradára, àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọdọ̀ gbọ́ràn sìi lẹ̀nu pẹ̀lú gbogbo ọ̀wọ̀. 5 Nítorí tí arákùnrin kan kò bá le è mójútó ilé ara rẹ̀, báwo ni yóò ṣe mójútó ilé Ọlọ́run? 6 Kò gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ titun, kí ó má baà gbéraga. Kí ó sì subú sínú ìdálẹ́bi bíi èsù. 7 Ó gbọdọ̀ ní ẹ̀rí tí ó dára pẹ̀lú ará àdúgbò, kí ó má baà bọ́ sínú ìtìjú àti pańpẹ́ èsù. 8 Àwọn díákónì, pẹ̀lú gbọdọ̀ lọ́lá, kìí se ẹlẹ́nu méjì. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí para tàbí olójú kòkòrò. 9 Wọ́n gbọdọ̀ pa òtítọ́ ìgbàgbọ́ tí a fi hàn mọ́ pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. 10 Wọ́n gbọdọ̀ kọ́kọ́ di ẹni ìtẹ́wọ́gbà, nígbànáà wọ́n gbọdọ́ ṣe isẹ́ ìránṣẹ́ nítorí wọn kò lẹ́bi. 11 Àwọn obìnrin lọ́nà kan náà gbọdọ̀ lọ́lá. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ̀ oníwọ̀ntunwọ̀nsì àti olóòtọ́ ní gbogbo ọ̀nà. 12 Àwọn díákónì gbọdọ̀ jẹ́ ọkọ oní ìyàwó kan. Wọ́n gbọdọ̀ le ṣe àmójútó àwọn ọmọ wọn àti ilé wọn dáradára. 13 Nítorí àwọn tì ó ti sìn dáradára gba orúkọ rere àti ìgboyà ńlá nínú ìgbàgbọ́ tí ó wà nínú Krístì Jésù. 14 Èmi ń kọ àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ọ, mo sì ní ìrètí láti tọ̀ ọ́ wá láìpẹ́. 15 Ṣùgbọ́n tí ó bá pẹ́ mi, èmi ń kọ̀wé kí o ba le mọọ bí a ti ń wùwà láàrín àwọn ènìyàn Ọlọ́run, tíí ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, òpó àti àtìlẹ́yìn òtítọ́. 16 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le jiyàn wípé ìjìnlẹ̀ ńlá ni òtítọ́ ti Ọlọ́run ii hàn. " Ó fara hàn nínú ẹran ara, ó gba ìdáláre nípa Ẹ̀mí, àwọn ángẹ́lì rí i, wọ́n kéde Rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀ èdè, asì gbà á sókè nínú ògo.