Orí Kejì

1 v 1 Ǹjẹ́ sááju ohun gbogbo, mo rọ̀ yín pé kí ẹ má a bẹ̀bẹ̀, gbàdúrà, ṣìpẹ̀ àti dúpẹ́ fún gbogbo ènìyàn, 2 fún àwọn ọba àti àwọn tó wà ní ipò àsẹ, kí àwa leè maa gbé ní àláfíà àti ìdákérọ́rọ́ ní ìwà bí Ọlọ́run àti iyì. 3 Èyí dára ósì jẹ́ ìtèwọ̀gbà níwájú Ọlọ́run Olùgbàlà. 4 Ó fẹ́ kí á gba gbogbo ènìyàn là àti pé kí wọ̀n sì mọ òtítọ́. 5 Nítorí Ọlọ́run kan ni ó wà, alárinnà kan ni ó sì wà làárín Ọlọ́run àti ènìyàn, ọkùnrin náà Krístì Jésù. 6 Ó fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní ìràpadà fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí ní àkókò tí ó tọ́. 7 Fún ìdí èyí, a sọ èmi tìkaraàmi di ìránsẹ́ ati àposítélì. Èmí ń sọ òtítọ́. Èmi kò parọ́. Èmi jẹ́ olùkọ́ àwọn Hélénì ni ìgbàgbọ́ àti ní òtítọ́. 8 Nítorínà, kí gbogbo ènìyàn níbi gbogbo máa gbàdúra àti kí wọ́n sì gbé ọwọ́ sókè ní àìsí ìbínú ati àríyànjiyàn. 9 Bákannáà, mo fẹ́ kí àwọn obìnrin máa wọ ara wọn ní asọ tí ó tọ́nà, ní ìwọ̀ntunwọ̀nsì àti ní ìkoraẹni-ní-ìjanu. kìí ṣe níti irun dídí, tàbí wúrà, tàbí ọ̀ṣọ́, tàbí asọ olówó-iyebíye. 10 Kí wọ́n máa wọ ohun tí ó tọ̀ọ̀nà fún obìnrin tó ń kéde ìwàbí-Ọlórun nípa iṣẹ́ rere. 11 Óyẹ kí obìnrin máa kẹ́ẹ̀kọ́ ní ìdàkẹ́jẹ́ àti nínú ìgbọràn gbogbo. 12 Èmi kò gba obìnrin láàyè láti kọ́ni tàbí ṣe ìsàkoso lé okùnrin lórí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbé ní ìdàkẹ́jẹ́. 13 Nítorí Ádámù ni akọ́kọ́ dá kí, á tó dá Éfà. 14 A kò tan Ádámù jẹ ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn jẹ pátápátá sínú àìsedédé. 15 Síbẹ̀síbẹ̀, a ó gbàálà nípa ọmọ bíbí, bí wọ́n bá tẹ̀sìwájú nínú ìgbàgbọ́, àti ìfẹ́ ati ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú ọkàn tí ó péye.