Orí Kẹta

1 Níparí, ẹ̀yin ará mi, ẹ yọ̀ nínú Olúwa. Kò ni mí lára láti kọ̀wé àwọn nǹkan woǹyí kan nán aǹ sí yín lẹ́kàn náà si. Àwọn nǹkan wọ̀nyí yíò pa yín mọ́. 2 Ẹ ṣọ́ra fún àwọn ajá. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn oníṣẹ́ ibi. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn tí wọ́n ń panilára. 3 Nítorí àwa ni olùkọlà. Àwa ni à ń sìn nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run. Àwa ni à ń ṣògo nínú Krístì Jésù, tí a kò sì gbékẹ̀lé ẹran ara. 4 Bẹ́ẹ̀ sì ni, èmi pẹ̀lú le gbékẹ̀lé ẹran ara. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun le gbékẹ̀lé ẹran ara, èmi pẹ̀lú le ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. 5 A kọ mí nílà ní ọjọ́ kẹjọ, ojúlówó ọmọ Ísráẹ́lì, láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámẹ́nì, ògidì Hébérù; níti òfin, Farisí ni mí. 6 Níti ìtara, mo gbógun ti ìjọ; níti òdodo lábẹ́ òfin, èmi kò lábùkù. 7 Ṣùgbọ́n mo ti ka gbogbo àwọn ohun tí ó jẹ́ èrè fún mí kún àdánù nítorí Krístì. 8 Kódà, nísinsìnyí mo ka ohun gbogbo kún àdánù nítorí ìmọ̀ Jésù Krístì Olúwa mi níye lórí ju ohun gbogbo lọ. Nítorí Rẹ̀ mo ti da ohun gbogbo sí ààtàn. Mo kà wọ́n sí ẹ̀gbin kí èmi kí ó le fi Krístì ṣèrè jẹ. 9 kí á sì lè rí mi nínú Rẹ̀. Èmi kò ní òdodo ti ara mi láti inú òfin. Kàkà bẹ́ẹ̀, òdodo mi jẹ́ èyí tí ó wá láti ipasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Krístì, òdodo ti ó wá láti ọdọ Ọlọ́run tí ó fìdí múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. 10 Ǹjẹ́ nísinsìyí èmi fẹ́ mọ̀ Ọ́ àti agbára àjíǹde Rẹ̀ àti ìfarakínra àwọn ìjìyà Rẹ̀. Mo fẹ́ kí á yí mi padà sínú ìrísí ikú Rẹ̀, 11 kí èmi kí ó le ní ìrírí àjíǹde kúrò láàrin àwọn òkú. 12 Kìí ṣe pé mo ti gba àwọn nǹkan wọ̀nyí, tàbí pé mo ti di pípé. Ṣùgbọ́n èmi ńlàkàkà kí èmi kí ó le ṣe àrígbámú ohun tí Krístì Jésù torí rẹ̀ gbámimú. 13 Ẹ̀yin ará, èmi kò rò pé èmi tìkara mi ti ṣe àrígbámú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun kan ni o: mò ń gbàgbé ohun tí ó ti bọ́ sẹ́yìn mo sì ń nàgà wo ohun tó wà lọ́ọ̀ọ́kán. 14 Mò ń lépa àfojúsùn náà láti le gba èrè ìpè gíga ti Ọlọ́run nínú Krísti Jésu. 15 Gbogbo àwa tí a ti dàgbà, ẹ jẹ́ kí á ma ronú báyìí; bí o bá sì fi ojú mìráǹ wo ohunkohun, Ọlọ́run yíò fi èyí náà hàn ọ́. 16 Ṣùgbọ́n ṣá, ohunkohun tí ọwọ́ wa bá ti bà, ẹ jẹ́ kí á dìí mú ṣinṣin. 17 Ẹ má a ṣe àfarawé mi, ẹ̀yin ará. Ẹ má a ṣe àkíyèsí àwọn tí wọ́n ń rin déédé pẹ̀lú àpẹrẹ tí ẹ ní nínú wa. 18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ńrìn -- àwọn tí mo ti máa ńsọ nípa wọn fún un yín, tí mo sì tún sọ fún un yín báyìí pẹ̀lú omijé -- bí àwọn ọ̀tá àgbélèbú Krístì. 19 Ìparun ni àtunbọ̀tán wọn. Nítorí ikùn wọn ni ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú àwọn ohun ìtìjú wọn. Ohun ayé ti gba ọkàn wọn. 20 Ṣùgbọ́n ìlú ìbílẹ̀ wa ń bẹ ní ọ̀run, láti ibití àwa ti ń retí Olùgbàlà kan, Jésù Krístì Olúwa. 21 Yíò pa àwọn ara yẹpẹrẹ wa yí dà si èyí tí a dá ní ìrísí ara ògo tirẹ̀, èyí tí a dá nípa ipá agbára Òun tìkara Rẹ̀ láti mú kí ohun gbogbo kí ó wà lábẹ́ ìsàkóso Rẹ̀.