Orí Kejì

1 Bí ìgbaniníyànjú kan bá wà nínú Krístì, bí ìtùnú kan bá wà nínu ìfẹ́ Rẹ̀, bí ìfarakínra kankan bá wà pẹ̀lú Ẹ̀mí, bí àánú àti ìkáàánu kan bá sì wà, 2 ǹjẹ́ ẹ mú ayọ̀ mi kún nípa ríronú bákan naa, níní ìfẹ́ kan naa, níní ìrẹ́pọ̀ ti ẹ̀mí, àti níní àfojúsùn kan náà. 3 Ẹ máṣe ṣe ohunkóhun nínú ìmọtara-ẹni-nìkan tàbi ìgbéraga. Kàkà bẹ́ẹ̀ nínú ìrẹ̀lẹ̀ ẹ ka elòmíràn kún ju ara yín lọ. 4 Kí olúkúlùkù yín máa tán àìní àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú, kí ó má sì ṣe tán ti ara rẹ̀ nìkan. 5 Ẹ máa ronú gẹ́gẹ́ bí Krístì Jésù ti ronú. 6 Bí Ó tilẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run, Òun kò rò pé ìbádọ́gba pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ohun tí à bá gbéléjú. 7 Kàkà bẹ́ẹ̀, Ó da ohun gbogbo sílẹ̀. Ó sì gbé àwọ̀ ẹrú wọ. Ó farahàn ní ìrísí ènìyàn. A sì rí I bíi ènìyàn. 8 Ó rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀ Ó sì gbọ́ràn títí dé ojú ikú, àní ikú orí àgbélèbú! 9 Fún ìdí èyí Ọlọ́run pàápàá wá gbé E ga gidi gan. Ó fún Un lórúkọ tó borí gbogbo orúkọ. 10 Ó ṣe èyí kí ó le jẹ́ pé ní orúkọ Jésù gbogbo erúnkún yóò máa wólẹ̀, àwọn tó wà lọ́run àti àwọn tó wà lórí ilẹ̀ àti àwọn tó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. 11 Ó ṣe èyí kí gbogbo ahọ́n le jẹ́wọ́ pé Jésù Krístì ni Olúwa, fún ògo Ọlọ́run Baba. 12 Ǹjẹ́, ará mi olùfẹ́, gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe má n gbọ́ràn nígbà gbogbo, kìí ṣe nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nìkan ṣùgbọ́n nígbà tí èmi kò sí nítòsí, ẹ jára mọ́ iṣẹ́ ìgbàlà yín pẹ̀lú ẹ̀rù àri ìwárìrì. 13 Nítorí Ọlọ́run ló ń mú kí ó wù yín láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ tí ó sì tún n ró yín lágbára láti ṣe é. 14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú tàbí àríyànjiyàn. 15 Ẹ hùwà báyìí kí ẹ̀yin kí o le di aláìléèéri àti olótítọ́, àwọn ọmọ Ọlọ́run tí kò lábàwọ́n. Ẹ hùwà báyìí kí ẹ̀yin kí o le tàn bíi ìmọ́lẹ̀ nínú ayé, láàrin ìran tí kò tọ́ tí iyè wọn sì ti ra. 16 Ẹ di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin kí èmi kí ó le nídìí láti ṣògo lọ́jọ́ Krístì. Nítorí nígbà náà ni èmi yóò mọ̀ pé èmi kò lépa lásán bẹ́ẹ̀ sì ni n kò ṣe làálàá lásán. 17 Ṣùgbọ́n bí a bá tilẹ̀ tú mi jáde mí bíi ọrẹ sórí ẹbọ àti iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, èmí yọ̀, èmí yóò sì yọ̀ pẹ̀lú gbogbo yín. 18 Bákannáà kí ẹ̀yin kí ó yọ̀, kí ẹ sì yọ̀ pẹ̀lú mi. 19 Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí nínú Jésù Olúwa láti rán Tìmótíù sí yín láìpẹ̀ yìí, kí èmi kí ó le ní ìmúlọ́kànle nígbàtí mo bá mọ bí ǹkan ṣe ń lọ pẹ̀lú yín. 20 Nítorí èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ yín ká lára nítòótọ́. 21 Nítorí gbogbo wọn ń lépa àwọn ìfẹ́ ọkàn tara wọn, wọn kò sì lépa àwọn ǹkan ti Jésù Krístì. 22 Ṣùgbọ́n ẹ̀yín mọyì rẹ̀, pé bí ọmọ ti ń sin baba, bẹ́ẹ̀ni ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú mi nínú ìhìnrere. 23 Nítorí náà mo ń gbèrò láti rán an sí yín ní kété tí mo bá mọ bí ǹkan ṣe ń lọ pẹ̀lú mi. 24 Ṣùgbọ́n ọkàn mi balẹ̀ nínú Olúwa pé èmi pàápàá kò ní pẹ́ yọjú sí yín fúnrara mi. 25 Ṣùgbọ́n mo rò pé ó yẹ kí n rán Ẹ̀páfródítù padà sí yín. Arákùnrin mi ni, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi ni, akẹgbẹ́-ọmọ-ogun ni pẹ̀lú mi, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ ìráńṣẹ́ yín tí ó ń mójútó àwọn àìní mi. 26 Nítorí tí ọkàn rẹ̀ pòrurù gidi gan, ó sì ń jarán láti wà pẹ̀lú yín nítorí tí ẹ gbọ́ pé ara rẹ̀ kò yá. 27 Lóòótọ́ ni pé ó ṣe àìsàn dé ojú ikú. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣàánú fún un, kì í sì ṣe fún òhun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi náà, kí ìbànújẹ́ mi má baà peléke síi. 28 Nítorí náà ó yámilára láti rán an sí yín, pé kí ẹ̀yin kí ó le yọ̀ nígbà tí ẹ bá rí i, kí ọkàn mi sì lè fúyẹ́. 29 Ẹ kí Ẹ̀páfródítù káàbọ̀ nìnú Olúwa pẹ̀lú ayọ̀. Ẹ máa bu ọlá fún àwọn ènìyàn bíi tirẹ̀. 30 Nítori iṣẹ́ Krístì ni ó fi fẹ́ẹ̀ kú. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti sìn mí àti láti dí ààyè ohun tí ẹ̀yin kò lè mójútó nípa iṣẹ́-ìsìn yín sí mi.