Orí Kẹta

1 Rán wọn létí láti máa tẹríba fún àwọn adarí àti àwọn alásẹ, láti gbó ti wọn, àti láti múra sílẹ̀ fún isẹ́ rere gbogbo. 2 Rán wọn létí kí wọ́n má se sọ ọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni lẹ́yìn, kí wọ́n yàgò fún ìjà, kí wọ́n jẹ́ kí àwọn ènìyàn ní ìfẹ́ ọkàn wọn, kí wọ́n máa fi ìwà tútù hàn sí gbogbo ènìyàn. 3 Nítorí àwa pẹ̀lú ti jẹ́ aláì-nírònú àti aláìgbọ́ran nígbà kan rí. A di asáko a sì dì wá ní ìgbèkùn sí afẹ́ ayé àti ìfẹ́kúfẹ̌. À ń gbẹ́ ńnú ibi àti ìlara. A jẹ́ ẹni ìlara a sì kórira ẹnikejì. 4 Sùgbọ́n nígbà tí ìsoore Ọlọ́run Olùgbàla wa àti ìfẹ́ rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn farahàn, 5 kìí se nípa isẹ́ òdodo tí a se, sùgbọ́n nípa ìfẹ́ rẹ̀ ni ó gbà wá. Ó gbà wá nípa ìwẹ̀nùmọ́ titun àti ìsọdòtun nípa ti Ẹ̀mí Mímọ́. 6 Ọlọ́run da Ẹ̀mí MÍmọ́ sí wa lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ nípasè Olúgbàla wa Jésù Kristì. 7 Ó se èyí, nígbà tí a ti dá wa láre nípa ore-ọ̀fẹ́, kí á le jẹ́ ajogún nípasè ìgboyà ayérayé. 8 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀. Mo fẹ́ kí ẹ sọ̀rọ̀ ǹǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú ìdánilójú, kí àwọn tí ó gba Ọlọ́run gbọ́ pinu lórí isẹ́ rere tí ó fi sí iwájú wọn. Àwọn nǹkan wọ̀nyí dára wọ́n sí se àǹfàní fún ènìyàn gbogbo. 9 Sùgbọ́n yàgò fún àríyànjiyàn agọ̀ àti ìtàn ìran àti asọ̀ àti ìjà nípa ti òfin. Aláìlérè àti asán ni àwọn nǹkan wọn nì. 10 Kọ ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fa ìyapa láàrín yín, lẹ́yín ìkìlọ̀ kan tàbí ìkejì, 11 kí o sì mọ̀ pé irú ẹni bé è ti yapa ó sì ń sẹ̀ ó sì dá ara rẹ̀ lẹ́bi. 12 NÍgbà tí mo bá rán Artemasi tàbí Tikiku sí ọ, yára wá sí ọ̀dọ̀ mini Nikoploisi, níbi tí mo ti pinu láti lo àkókó òtútú mi. 13 Yára kí o rán Ṣenasi, amòfin, àti Apollo, nií ọ̀nà tí wọn kò ní se aláìní ohunkóun. 14 Kí àwọn ènìyàn wá kọ́ láti máa se isẹ́ rere ti ó ń bá àìní pàdé kí wọ́n má baà jẹ́ aláìléso. 15 Gbogbo àwọn tí ó wà pèlú mi kíi yín. E kí àwọn tí ó nífẹ̌ wa nínú ìgbàgbọ́. Kí ore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo yín.