Orí kejì

1 Ṣùgbọ́n ìwọ, máa sọ ohun tí ó yẹ sí ìtọ́ni tí ó yè koro. 2 Àgbàlagbà okùnrin gbọdọ̀ jẹ́ oní-wọ̀n-tun-wọ̀nsì, ẹni-ọ̀wọ̀, ọlọgbọ́n, ẹni tí ó yẹ̀ koro nínú ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìpamọ́ra. 3 Kí àgbàlagbà obìnrin jẹ́ ẹni ọ̀wọ̀, kí íse ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn. kí wọ́n máa se di ẹrú sí ọtí mímu. kí wọ́n kọ́ oun tí ó dára 4 láti lè kọ́ àwọn obìnrin kékeré láti nífẹ̌ ọkọ wọn àti ọmọ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́. 5 kí wọ́n kọ́ wọn láti jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé, ẹni mímọ́, alámojútó ilé, àti ẹni tí ó ń gbọ́ràn sí ọkọ wọn lẹ́nu. Wọ́n gbọdọ̀ se èyí kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má ba à di sísọ̀rọ̀ òdì sí. 6 Ní ọ̀nà kannǎ, gba àwọn okùnrin kékeré níyànjú láti jẹ́ ọlọ́pọlọ-pípé. 7 Ní ọ̀nà gbogbo fi ara rẹ hàn ní àpẹẹrẹ isẹ́ rere; àti nígbà tí ìwọ bá ń kọ́ni, fi ìwà òtítọ́ àti àgbà hàn. 8 Sọ ọ̀rọ̀ tí ó yè koro àti aláìlẹ́bi, kí ojú le è ti ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì si, nítorí kò ní ohun búburú kan láti sọ nípa wa. 9 Ó yẹ kí ẹrú gbọ́ràn sí ọ̀gá rẹ̀ lẹ́nu nínú ohun gbogbo. Ó yẹ kí wọ́n wù wọ́n dípò báwọn jiyàn. 10 Kí wọn kí ó má se ìrẹ́jẹ. Dípò bẹ̌, kí wọn kí ó fi ìgbàgbọ́ rere hàn, tó bè ní gbogbo ọ̀nà kí wọn kí ó le se ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Olúgbàlà wa tí à ń kọ̀ ní ọ̀sọ́. 11 Nítorí ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti farahàn sí gbogbo ènìyàn. 12 Ó ń kọ́ wa láti lòdì sí àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̌ ayé. Ó ń kọ́ wa láti gbé orí pípé, lí òdodo, àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsìyí 13 nígbà tí à ń fojú sọ́nà láti gba ìrètí ìbùkún wa, ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jèsu Kristì. 14 Jésù fi ara rẹ̀ fún wa láti rà wá padà kúrò nínú ẹ̀sẹ̀ gbogbo àti láti yà wá sí mímọ́, fún ara re, ènìyàn tí ó yátọ̀ tí ó ní ìtara fún isẹ́ rere. 15 Nǹkan wọ̀nyí ni kí ìwọ kí ó máa sọ kí o sì gba ni níyànjú. Máa fi àsẹ gbogbo bá ni wí. Mà se jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó gàn ọ́.