Orí Kẹta

1 Nísinsìnyí, mò ń kọ ìwé síiyín, ará, ìwé kejí yii gẹ́gẹ́ bíi ìrántí làti rú ọkàn òdodo yín sókè, 2 kí ẹ̀yin bà lè rántí ọ̀rọ̀ tí a sọ látẹ̀yìn wá nípa àwọn wòlíì mímọ́ àti àṣẹ tí Olúwa àti Olùgbàlà tí a fún wa nípa àwọn àpóstélì yín. 3 Àkọ́kọ́ ẹmọ èyí, wípé àwọn olùkẹ́gàn yóò wá ní ọjọ ìkẹhìn. Wọ́n yóò kẹ́gàn àti tẹ̀síwájú nínú ìfẹ́ ọkàn wọn. 4 Wọn yóò wípé, ‘’Ìlérí ìpadàbọ̀ rẹ̀ dà? Nígbàtí àwọn bàbá wa sún orun, gbogbo ǹkan tí wà bẹ́ẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ísẹ̀dá.’’ 5 Tìfẹ́tìfẹ́ wọ́n gbàgbé wípé ọ̀run àti ayé tẹ̀lẹ̀ láti inú omi àti nípa omi tipẹ́tipẹ́ nípa àsẹ Ọlọ́run , 6 àti nípa àwọn wọ̀nyí, ayé ìgbànáà dí ìparun, pẹ̀lú ìkún omi. 7 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí àwọn ọ̀run àti ayé wà ní ìpamọ́ fún iná nípa òfin kanáà. Wọ́n wà ni ìpamọ́ fún ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun tì àwọn ènìyàn aláíwà bi Ọlórun. 8 Kò gbọdò kúrò ní àkíyèsí rẹ́, ará, wípé ọjọ́ kan pẹ̀lú Olúwa dàbíi ẹgbẹ̀rún ọdún, ẹgbẹ̀rún ọdún sí dàbíi ọjọ́ kan. 9 Olúwa kìí jáfara sí ìlérí rẹ̀, bí àwọn ǹkan ṣe ka àìjáfara sí. Dípò, ó ní sùrúù síi yín. Kò wú nínu ìfẹ́ rẹ̀ láti jẹ́ kí ìkankan nínú yín parun, ṣùgbọ́n kí gbogbo ènìyàn fàyè gba fún ìrònúpìwàdà. 10 Síbẹ̀síbẹ̀, ọjọ́ Olúwa yóò de bí olè: Àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò jóná pẹ̀lú iná, àti ayé àti isẹ́ rẹ̀ yóò di ífihàn. 11 Nígbàti ósì ti jẹ́ pe àwọn ǹkan wọ̀n yìí ni a ó parun ní ọ̀nà yí. Irú ènìyàn wo ni ẹ ó jẹ̀ẹ́? Kí ẹ gbé ìgbéayé mímọ àti ìgbéayé ìwà bíi Ọlọ́run. 12 Kí ẹ palẹ̀mọ́ kí ẹ sì ṣọ́na fún bíbọ̀ ọjọ́ Olúwa. Ní ọjọ́ nà, àwọn ọ̀run yóò di píparun pẹ̀lú iná, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ni a ó yọ́ pẹ̀lú ooru gbígbónán girigiri. 13 Ṣùgbọ́n nípa ìlérí Rẹ̀ àwa n dúró de ọ̀run titun àti ayé titun, níbití òdodo yóò gbé wà. 14 Nítorínà, olùfẹ́, nígbàtí ẹ sì ń retí nkán wọ̀nyí, ẹ sa ipá yín láti wà nì aláìlábàwọ́n àti aláìlábùkù ní iwájú Rẹ̀, ní àláfíà. 15 Bẹ́ẹ̀ni kí ẹ rí sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà, bí olùfẹ́ arákùnrin Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé síi yín, bíi ọgbọ́n tí a fi fún-un. 16 Pọ́ọ̀lù sọ gbogbo ǹkan wọ̀nyí nínú àwọn lẹ́ẹ̀ta rẹ̀, nínú èyí tí àwọn ohun kọ̀kan ṣòro láti nì òye rẹ̀. Ọkùnrin aláímọ̀kan àti oníṣégeṣège túmọ̀ àwọn ǹkan wọ̀nyí, bí wọ́n ṣeṣe àwọn ìwé mímọ́ míràn, sí ìparun ti wọn. 17 Nítorínà, ará, níwọ̀n tí ẹmọ àwọn ǹkan wọ̀nyí, ẹ pa ara yín mọ́ kí ẹ má ba lè sọnù pẹ̀lú ẹ̀tàn àwọn ènìyàn aláípòfinmọ́ kí o sìi pàdánù òtítọ́ rẹ. 18 Ṣùgbọń ẹ dàgbà nínu ore-ọ̀fẹ́ àti ìmọ̀ Ọlúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì. Kí ògo kó jẹ́ tí Rẹ̀ nísinsìnyí àti títí láíláí. Àmín