Orí Kejì

1 Àwọn wòlíì èké tọ àwọn ènìyàn wá, àti àwon olùkọ́ èké yóò sì tọ̀ yín wá.Wọn ó fi ìkọ̀kọ̀ mú ìparun èké pẹ̀lú wọn wá, wọn yó sì sẹ́ olúwa wọn eni tí ó ràn wọ́n. Wọ́n sì mú ìparun wá sórí ara wọn. 2 Púpọ̀ ni yóó tẹ̀lé ìfẹ́kùfẹ́ wọn, àti nípa wọn ọ̀nà òtítọ́ yóò sì di búburú. 3 Pẹ̀lú wòbìà wọ́n yò jẹ èrè lára yín pẹ̀lú ọ̀rọ́ ẹ̀tàn. Ìdálẹ́bi wọn kò kín pẹ́ títí; ìparun wọn kò kín-ń sùn. 4 Nítorí Ọlọ́run kò dá àwọn áńgẹ́lì tó ṣẹ̀ láre. Dípò ó fi wọ́n lé Tátárúsì lọ́wọ́ láti wà ní ìpamọ́ ẹ̀wọ̀n tí òkùnkùn-abẹ títí di ìdájọ́. 5 Bákanáà, kò dá àwọn ayé àtijọ́ láre. Dípò, ó pa Nóàh mọ́, tó jẹ́ olùpolongo òdodo, pẹ̀lú àwọn méje míì, nígbàtí ó mú ìkun omi wá sóríi ayé àwọn aláìwà bíi Ọlọ́run. 6 Ọlọ́run túnbọ̀ dín ìlú Sódọ́mù àti Gòmórrà kú sí ẹ́rú ósìi dá wọn lẹ́bi ìparun, gẹ́gẹ́ bi àpẹẹrẹ oun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwon aláíwà bíi Ọlọ́run. 7 Ṣùgbọ́n fun Lóòtì olódodo, tí wọ́n nilára pẹ̀lu ìwà àwọn ènìyàn arufin nínu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, Ọlọ́run kóoyọ. 8 Fún ọkùnrin olódodo náà, tí ńgbé ní àrin wọn ní ọjọ́ dé ọjọ́, la pọ́n lójú ní ọkàn òdodo rẹ̀ nítorí ǹkan tí ó rí àti tí ó gbọ́. 9 Olúwa mọ bí ó tín yọ àwon ènìyàn bí Ọlọ́run kúrò nínu ìdánwò, àti láti mú àwọn ènìyàn aláìsòdodo fún ìjìyà ní ọjọ́ ìdájọ́. 10 Èyíì pàápàá jẹ́ òtọ́ọ́ fún àwọn tí ó ńtẹ́sìwájú nínú ìpòngbẹ búburú ti ara àti tí ngán àsẹ. Wọ́n jẹ́ àlágídí àti aládàámọ̀. Ẹ̀rù kò bà wọ́n láti lòdì sí àwọn ológo. 11 Àwon áńgẹ́lì ní okun àti agbára tí ó tóbi, ṣùgbọ́n wọn kìí nmú ìdájọ́ àbùkù wọn wá sí ọ̀dọ Ọlọ́run. 12 Ṣùgbọ́n àwon eranko àláìlọ́kan yìí wà fún mimu àti píparun.Wọ́n kò mọ oun tí wọ́n ń kàn lábùkù. A ó pawọ́n run. 13 Wọ́n yóò gba èrè iṣẹ́ ibi wọn. Wọ́n ró wípé ìgbádùn ní ọjọ́ jẹ́ ìdùnnú. Wọ́n ní ìdọ̀tí àti àbàwọ́n. Wọ́n máa ń gbádùn àwọn ìwà ẹ̀tàn wọn nígbàtí wọ́n bá ń jẹ àsè pẹ̀lú yín. 14 Wọ́n ní ojú tí ó kún fún panságà obìnrin; wọn kìí ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀. Wọ́n tan ọ́kàn tí kò dúró sínu iṣẹ́ ibi, àti ọkàn wọn ní atikó nínú ojúkókòrò.Wọ́n jẹ́ ọmọ-ègún! 15 Wọ́n ti kọ ọ̀nà òtítọ́ sílẹ̀. Wọ́n ti sọnù, wọ́n sì ti tẹ̀lé ọ̀nà Bálámù ọmọ Bósórì, tó fé láti gba owó fún àiṣòdodo. 16 Ṣùgbọ́n ó gba ìbáwí fún ìrékọjá rẹ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ odi kan tó ń sọ̀rọ̀ ní ohùn ènìyàn da asiwèrè wòlíì dúró. 17 Àwọn ọkùnrin yìí dàbí òrísun tí kó lómi. Wọ́n dàbí àwọsánmà tí ìjì wọ́ lọ. Òkùnkùn tó nípọn wà ní ìpámọ́ fún wọn. 18 Wọ́n sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìyájú asán. Wọ́n tan àwọn ènìyàn pẹ̀lú ìfẹ́kùfẹ́ tara. Wọ́n tan àwọn ènìyàn to ngbìyànjú láti sá kúrò lọ́dọ̀ `awon tó ngbé nínu àsíse. 19 Wọ́n sèlérí òmìnira fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn gan fún ra wọn jẹ́ ẹrú-ìbàjẹ́. Nítorí ènìyàn jẹ́ ẹrú sí ohunkóhun tó bá borí rẹ̀. 20 Ẹnikẹ́ni tó bá yọ nínú àìmọ́ ayé nípa ti ìmọ̀ Olúwa ati Olùgbàlà Jésù Krístì, tí ó sìí pàdà sí àwọn àìmọ́ yìí, ìpìnlẹ̀ kẹhìn ti di búburú fún wọn ju ti ìpìnlẹ̀ àkọ́kọ́ lọ. 21 Yó tìi dára fún wọn láti má mọ̀ọ ọ̀na òdodo ju kí wọ́n mòọ́ kí wọ́n sìi yà kúrò nínú àsẹ mímọ́ tí a fifún wọn. 22 . Òwe yìí jẹ́ òtítọ́ fún wọn: ‘’Ajá pàdà sí èébì rẹ̀. Ẹlẹ́dẹ̀ mímọ́ pàdà sí àbàtà.’’